Oriki Obàlúàiyé

29/03/2010 07:46

ÒRÌSÀ Jìngbìnì

Abàtà, Arú Bí Ewé Ajó.

ÒRÌSÀ Tí Nmú Omo Mú Ìyá

Obàlúàiyé Bá Mú Won Tán

O Tún Lè Sáré Lo Mú Bàbá

ÒRÌSÀ Bí Àjé

Obàlúàiyé Mo Ilé Osó, O Mo Ilé Àjé

O Gbá Osó L’ójú

Osó Kún Fínrínfínrín.

O Pa Àjé Ku Ìkan Soso

ÒRÌSÀ Jìngbìnì

Obàlúàiyé A Mú Ni Toùn Toùn

Obàlúàiyé Odù Re Hàn Mí

Kí Ndi Olówó

Kí Ndi Olomo.

Àse