Oriki Obàlúàiyé
29/03/2010 07:46
ÒRÌSÀ Jìngbìnì
Abàtà, Arú Bí Ewé Ajó.
ÒRÌSÀ Tí Nmú Omo Mú Ìyá
Bí Obàlúàiyé Bá Mú Won Tán
O Tún Lè Sáré Lo Mú Bàbá
ÒRÌSÀ Bí Àjé
Obàlúàiyé Mo Ilé Osó, O Mo Ilé Àjé
O Gbá Osó L’ójú
Osó Kún Fínrínfínrín.
O Pa Àjé Ku Ìkan Soso
ÒRÌSÀ Jìngbìnì
Obàlúàiyé A Mú Ni Toùn Toùn
Obàlúàiyé Sí Odù Re Hàn Mí
Kí Ndi Olówó
Kí Ndi Olomo.
Àse